Yoruba Public Library

Yoruba Public Library Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Yoruba Public Library, Library, 1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park, London.

Yorùbá Public Library (Ilé ìyáwèé/kàwé gbogbogbòò Yorùbá) jẹ́ àkọ́kọ́ Ilé ìyáwèé/kàwé ajẹmọ́dííjìtì tó kó àkótán lórí Ìmọ̀ àti àṣà Yorùbá.Lára àwọn ohun tó sódo sínú náà rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ ajẹmọ́dííjìtì ni:Ìwádìí, agbo-ajẹmọ́ọ̀wé, ilé ìkówèé-pamọ́ sí

YORÙBÁ PUBLIC LIBRARY Àṣà máa ń lapa, ó sì máa tọ́ ìhùwàsí àti ìṣesí ọlọ́danni lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá wáyé nígbà kéke...
01/09/2026

YORÙBÁ PUBLIC LIBRARY
Àṣà máa ń lapa, ó sì máa tọ́ ìhùwàsí àti ìṣesí ọlọ́danni lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá wáyé nígbà kékeré rẹ̀ àti lọ́jọ́ ogbó.
Dábòòbo àṣà rẹ kí o sì mọ iyì rẹ̀!

Culture helps to shape and guide an individual behaviour and attitude towards issues raised during his childhood and old age.
Protect and value your culture










A kú àfojúbà Oṣù Aláyọ̀Happy New Month!
01/09/2026

A kú àfojúbà Oṣù Aláyọ̀
Happy New Month!










ÀTÚNṢE ÀṢIPA ÒWE/CORRECTION OR WONG PROVERBKójú má ríbi gbogbo ara lòògùn rẹ̀❌Kójú má ríbi ẹsẹ̀ loògun rẹ̀✔️Ojú wa ni ẹ̀...
30/08/2026

ÀTÚNṢE ÀṢIPA ÒWE/CORRECTION OR WONG PROVERB
Kójú má ríbi gbogbo ara lòògùn rẹ̀❌
Kójú má ríbi ẹsẹ̀ loògun rẹ̀✔️

Ojú wa ni ẹ̀yà ara tí ó ga jù ní ara ènìyàn, ẹsẹ̀ ni ó wà ní ìsàlẹ̀ ara pátápátá. Kókó tí èyí ń tẹnumọ́ ni wípé ìbáṣepọ̀ wà láàárín ibi tí ó ga jù lára àti ibi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá.

So that the eyes may not see evil, the entire body is the remedy❌

So that the eyes may not see evil, the feet are the remedy.✔️

Implied meaning:
Although the eyes are at the apex of the body and the feet are at the very bottom, they depend on one another. Vision alone is powerless without movement, and movement determines what vision will encounter. What the feet choose to carry the body toward ultimately shapes what the eyes will see.










OÚNJẸ ILẸ̀ WA/OUR TRADITIONAL FOODSÀlapà jẹ́ oríṣìí oúnjẹ ìbílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ó farapẹ́ móínmóín.  àpapọ̀ ẹwà àti ẹ̀g...
28/08/2026

OÚNJẸ ILẸ̀ WA/OUR TRADITIONAL FOODS
Àlapà jẹ́ oríṣìí oúnjẹ ìbílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ó farapẹ́ móínmóín. àpapọ̀ ẹwà àti ẹ̀gúsí ni wọ́n fi ń ṣe é. Àwọn èròjà tí wọ́n fi ń sè é ni ẹ̀wà, ẹ̀gúsí, àlùbọ́sà, òróró, rodo, tàtàṣé, iyọ̀, amọ́bẹ̀dùn, omi, ẹja,edé àti ewéeran.

Alapa is a traditional Yorùbá cuisine, it is a steam pudding similar to móínmóín. It is the combination of beans and melon. The ingredients for àlapà are beans, melon , onions, oil bonnet and paprika pepper, salt, seasoning, water, fish, crayfish, wrapping leaf.









OMi ORÓKÈ ÒWU/OWU WATERFALLS 🌊 Omi Orókè Òwu wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódùn ní ìpínlẹ̀ Kwara, ó wà lágbègbè Ọwá Onírè àti ...
27/08/2026

OMi ORÓKÈ ÒWU/OWU WATERFALLS
🌊 Omi Orókè Òwu wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódùn ní ìpínlẹ̀ Kwara, ó wà lágbègbè Ọwá Onírè àti Ọwá Kájọlà. Ó jẹ́ ibùdó ìrìnàjò afẹ́ àdáyébá ayanilẹ́nu 🌿✨, ó sì wà lára àwọn omi Orókè tí ó ga jù lọ ní Apá ìwọ oòrùn Áfíríkà 🏞️💦.

Owu Waterfalls is located in Ifelodun Local Government Area of Kwara State, Nigeria, near the communities of Owa Onire and Owa Kajola. It is a breathtaking natural wonder 🌿💧 and is often celebrated as the tallest waterfall in West Africa 🏔️🌊.

🌍📚✨

ÈDÈ ÌPERÍ/YORÙBÁ LEXICON KỌ̀JẸ̀GBIN ni à ń pe àlàfo àtẹ́lẹsẹ̀ èèyàn lédè Yorùbá. The midfoot/arch area of the human feet...
25/08/2026

ÈDÈ ÌPERÍ/YORÙBÁ LEXICON
KỌ̀JẸ̀GBIN ni à ń pe àlàfo àtẹ́lẹsẹ̀ èèyàn lédè Yorùbá.

The midfoot/arch area of the human feet is known as KỌ̀JẸ̀GBIN in Yorùbá language.

















📷Stutterstock

25/08/2026

OLÓYÈ ALÀBÍ ÒGÚNDÉPÒ
Olóyè Àlàbí Ògúndépò jẹ́ àgbà-ọ̀jẹ̀ akéwì, òṣeré àti oníìjálá. Ọmọ bíbí ìlú Ṣakí ní Òkè -Ògùn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, orílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ èèkàn nínú àwọn oníjáálá ní ilẹ̀ Yorùbá, òun ló ṣẹ̀dá orin ìyìn ìlú Ṣakí láti fi ṣe ìgbélárugẹ ìlú rẹ̀. Àádọ́ta ọdún ó lé ní o fi ṣiṣẹ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣàn. Gbajú-gbajà agbédègbeyọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ni. Olùfẹ́ èdè, ìtàn àti àṣà Yorùbá ti ó ń fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ yálà ohun tàbí àpilẹ̀kọ ṣe ìgbélárugẹ ìran Yorùbá. Alabi Ògúndépò darapọ̀ mọ́ àwọn baba ńlá rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ọdún 2026 kí Elédùà bá wa tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere.

Chief Àlàbí Ògúndépò was a distinguished elder poet, actor, and oníìjálá (Ijala chanter). He was a native of Ṣakí in Òkè-Ògùn, Oyo State, Nigeria. He was one of the foremost oníìjálá in Yorùbáland and the creator of the Ṣakí anthem, composed to promote and celebrate his hometown. For over fifty years, he worked in radio and television and became a renowned broadcaster, widely known and loved by many. He was a passionate lover of the Yorùbá language, history, and culture, which he promoted through his works, both audio and written, contributing immensely to the preservation and advancement of Yorùbá heritage. Alàbí Ògúndépò joined his ancestors on the 24th of June, 2026. May Elédùà receive him into peaceful rest and grant him eternal peace.

IGÍ DÁ!Oníṣẹ́ ikú dé-é! Ikú ọ̀hún bàjẹ́ jàre,Gbogbo ọdẹ ní í pa bíi ẹran!Àwọn ọdẹ tí ń bẹ láyé,Ìṣọ̀lá Ìjí, wọn ò kúkú tó...
25/08/2026

IGÍ DÁ!
Oníṣẹ́ ikú dé-é! Ikú ọ̀hún bàjẹ́ jàre,
Gbogbo ọdẹ ní í pa bíi ẹran!
Àwọn ọdẹ tí ń bẹ láyé,
Ìṣọ̀lá Ìjí, wọn ò kúkú tó tọ̀run!
Àlàbí Ògún dara pọ̀, ó dìgbà!

Bá a bá dáyé, a kì í fẹ́ kú,
Gbogbo wa ti gbàgbé àdéhùn ni!
Ẹrú onígbàgbé làwa ènìyàn!
Ìṣọ̀lá Ìjí, ènìyàn ló gbàgbé sẹ́,
Ènìyàn ló gbàgbé-é, Olúwa rántí!

Níjọ́ ọ̀kín kú, lẹwà ọ̀kín rọ̀run!
Àlàbí Ògún ti gbóhùn àrà rèwàlẹ̀ àṣà!
Òkú ìkẹyìn, kó máa kí tìṣáájú!
Kí òkú ó máa kí òkú lọ́run!
Dákun o, máa bá mi kí bàbá mi!
Kó má sùn gbàgbé, kó má fọmọ rẹ̀ẹ́lẹ̀!

Ǹjẹ́, ó wá di gbéré, gbéré!
Ó di gbéré ọmọ aláré ọdẹ!
Ọdẹ kì í sunkún, ọdẹ kì í gbààwẹ̀!
Ìrèmọ̀jé lọdẹ fi í ṣorò lẹ́yìn ara wọn!
Ilẹ̀pa dòdò kó forí jòkú
Kórí inú ó dẹlẹ̀ fún tòde!

© Ayanwale MC Ghaabio Àyánwálé

ÒGÒGÓ KÒ KÚ, ỌMỌ KÚLÓDÒ PAPÒDÀ NITáíwò ò ò ò!Babátúndé ò ò ò! gbérańlẹ̀ o dìde.Ògògó  gbérańlẹ̀ bí ẹ̀rùgàlé .           ...
24/08/2026

ÒGÒGÓ KÒ KÚ, ỌMỌ KÚLÓDÒ PAPÒDÀ NI
Táíwò ò ò ò!
Babátúndé ò ò ò! gbérańlẹ̀ o dìde.
Ògògó gbérańlẹ̀ bí ẹ̀rùgàlé .
A tara kánkán a wá Hassan lọ
A tara ṣàṣà wá baba dé Ìkọ́ Àwúsí.
A rìn gbẹ̀rẹ̀ wa ọmọ Kúlódò dé Ìdòròmù Àwísẹ̀
A pọ̀sẹ̀sẹ̀ títí a dé Ìwọnràn tójúmọ́ tí n mọ́.
Igi dá a ò ri Èdúnjọbí Ọba Ọmọ.
Oyin ṣí lọ níkókó igi
Èèrùn ṣí lọ láàrin àgìyàn.
Táíwò àgbà-ọ̀jẹ̀ láàrin àwọn òṣeré
Ọmọ Hassan lọ láàrin àwọn ọlọ́pọlọ.
Ògbóǹtarìgì Òṣeré Baba Kírà rèwàlẹ̀ àṣà.
Agbé kú aró ń sunkún aró.
Àlùkò ṣàìsí osùn ń ṣọ̀fọ̀.
Lékéǹlèké kú ẹfun kira rẹ̀ sínú àrùwẹ̀
Ẹfun ń ṣomi lójú bí egbére.
Odídẹrẹ́mòfé kú epo pupa ń ṣèdárò.
Erin níí kú tí í feyín delé.
Ẹfọ̀n níí kú tí í fi pátákò sílẹ̀.
Táíwò kú iṣẹ́ rẹ̀ ń ṣẹ̀mí .
Títí ayé iṣẹ́ rẹ̀ ó sì máa bẹ.
Òótọ́ lonírèsé Ògògó ọmọ Kúlódò ti figbáálẹ̀
Táíwò ò lè fíngbá mọ́.
Àmọ́ igbá tí Babátúndé ti fín sílẹ̀ ò le è parun.
Igbá ayérayé igbá kánrinkése
Iṣẹ́ tí Táyélolú ṣe kò ní wọ̀ọkùn.
Àjànàkú Ògògó lọ gbogbo ìlú mì tìtì !
Táíwò Hassan ti ṣe tiẹ̀ ò pẹ̀yìndà
Ẹniire papòdà ẹniire lọ!
Èjìrẹ́ Òkìn wọ Ìgbálẹ̀ lọ!

The curtain has fallen, but your light remains.
Ògògó, some people pass through life; others leave footprints that time cannot erase. You belonged to the latter. Your journey may have ended, but the memories, laughter, wisdom and moments you gave us will continue to live in the hearts of all those you touched.
Today, we mourn your departure, but we also celebrate the life you lived and the legacy you leave behind.
The curtain has fallen,
but the lights remain on.
The applause continues,
and your legacy lives on.
Rest peacefully, Ogogo. Your final scene may have ended, but your story will never be forgotten.

©BBAkomonimo
©Dr. Adébàyọ̀wá Alimi-Adeniran








ORÚKỌ/NAMESOrúkọ a máa sọ ìtàn, fún ènìyàn ní òmìnira tàbí fi wọn sí ìgbèkùn. Orúkọ a máa ní ohun tó dúró fún; ìdí nìyí ...
22/08/2026

ORÚKỌ/NAMES
Orúkọ a máa sọ ìtàn, fún ènìyàn ní òmìnira tàbí fi wọn sí ìgbèkùn. Orúkọ a máa ní ohun tó dúró fún; ìdí nìyí tí àwọn Yorùbá fi máa ń sọ pé wèrè nìkan ni ìí bìkítà nípa orúkọ, tí ó sì máa ń kọtí ikún sí iyatọ̀ tí ó wà láàárín orúkọ tí ó yàn láti jẹ́ àti èyí tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti máa pè wọ́n.

Name tell stories, liberate or imprison. Names commit; which is why the Yorùbá say that it is only mad people who do not mind what names they are called or who refuse to see the difference between the names they choose to bear and the ones the world prefers to call them.

© Duro Adeleke









Address

1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park
London
N77PH

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Yoruba Public Library posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Organisation

Send a message to Yoruba Public Library:

Shortcuts

Share

Category